Jer 14:10-12
Jer 14:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere. Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run.
Jer 14:10-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia. Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”
Jer 14:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà OLúWA kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”