Jer 14:1-13

Jer 14:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

EYI li ọ̀rọ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah wá nipa ti ọdá. Juda kãnu ati ẹnu-bode rẹ̀ wọnnì si jõro, nwọn dudu de ilẹ; igbe Jerusalemu si ti goke. Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn. Nitori ilẹ, ti ndãmu gidigidi, nitoriti òjo kò si ni ilẹ, oju tì awọn àgbẹ, nwọn bo ori wọn. Lõtọ abo-àgbọnrin pẹlu ni papa bimọ, o fi i silẹ nitori ti kò si koriko. Ati awọn kẹtẹkẹtẹ-igbẹ duro lori oke wọnni, nwọn fọn imu si ẹfũfu bi ikõko, oju wọn rẹ̀ nitoriti kò si koriko. Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀. Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn? Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ. Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere. Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi.

Jer 14:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí: “Juda ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira. Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè. Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi, àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi. Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo, ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn, wọ́n káwọ́ lérí. Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ, nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà, ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí. Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, nítorí kò sí koríko. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè, wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko. Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko. Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́. Ìwọ ìrètí Israẹli, olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà? Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú? Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá; bí alágbára tí kò lè gbani là? Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA, a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá, má fi wá sílẹ̀.’ ” OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia. Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.”

Jer 14:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn: “Juda káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu. Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn. Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà; ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn. Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i OLúWA, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ. Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré? Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, OLúWA, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀. Báyìí ni OLúWA sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà OLúWA kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.” Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”