Jer 10:1-25

Jer 10:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun nyin, ẹnyin ile Israeli: Bayi li Oluwa wi, Ẹ máṣe kọ́ ìwa awọn keferi, ki àmi ọrun ki o má si dãmu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ède. Nitori asan ni ilana awọn orilẹ-ède; nitori igi ti a ke lati igbo ni iṣẹ ọwọ oniṣọna ati ti ãke. Nwọn fi fádaka ati wura ṣe e lọṣọ, nwọn fi iṣo ati olù dì i mu, ki o má le mì. Nwọn nàro bi igi ọpẹ, ṣugbọn nwọn kò fọhùn: gbigbe li a ngbe wọn, nitori nwọn kò le rin. Má bẹ̀ru wọn; nitori nwọn kò le ṣe buburu, bẹ̃li ati ṣe rere, kò si ninu wọn. Kò si ẹnikan ti o dabi Iwọ Oluwa! iwọ tobi, orukọ rẹ si tobi ni agbara! Tani kì ba bẹ̀ru rẹ, Iwọ Ọba orilẹ-ède? nitori tirẹ ni o jasi; kò si ninu awọn ọlọgbọ́n orilẹ-ède, ati gbogbo ijọba wọn, kò si ẹniti o dabi Iwọ! Ṣugbọn nwọn jumọ ṣe ope ati aṣiwere; ìti igi ni ẹkọ́ ohun asan. Fadaka ti a fi ṣe awo ni a mu lati Tarṣiṣi wá, ati wura lati Upasi wá, iṣẹ oniṣọna, ati lọwọ alagbẹdẹ: alaro ati elese aluko ni aṣọ wọn: iṣẹ ọlọgbọ́n ni gbogbo wọn. Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀. Bayi li ẹnyin o wi fun wọn pe: Awọn ọlọrun ti kò da ọrun on aiye, awọn na ni yio ṣegbe loju aiye, ati labẹ ọrun wọnyi. On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀. Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá. Aṣiwere ni gbogbo enia nitori oye kò si: oju tì olukuluku alagbẹdẹ niwaju ere rẹ̀, nitori ère didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu rẹ̀. Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: nigba ibẹwo wọn nwọn o ṣègbe. Ipin Jakobu kò si dabi wọn nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo; Israeli si ni ẹya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀. Ko ẹrù rẹ kuro ni ilẹ na, Iwọ olugbe ilu ti a dotì. Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i. Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u. Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi. Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka. Sa wò o, ariwo igbe ti de, ati irukerudo nla lati ilẹ ariwa wá, lati sọ ilu Judah di ahoro, ati iho ọwawa. Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀. Oluwa kilọ fun mi, ṣugbon ni idajọ ni, ki o máṣe ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má sọ mi di asan. Tu ibinu rẹ si ori awọn orilẹ-ède, ti kò mọ̀ ọ, ati sori awọn idile ti kò ke pè orukọ rẹ, nitoriti nwọn ti jẹ Jakobu run, nwọn si gbe e mì, nwọn si pa a run tan, nwọn si sọ ibugbe rẹ̀ di ahoro.

Jer 10:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: OLUWA ní, “Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn, nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn. Wọn á gé igi ninu igbó, agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ. Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀, kí ó má baà wó lulẹ̀. Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí, wọn kò lè sọ̀rọ̀, gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọn nítorí pé wọn kò lè dá rìn. Ẹ má bẹ̀rù wọn nítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.” OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba, agbára orúkọ rẹ sì pọ̀. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni; kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọ láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè, ati ni gbogbo ìjọba wọn. Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn, ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n, nítorí igi lásán ni. Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi, ati wúrà láti ìlú Ufasi. Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n, ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà. Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupa ati ti elése àlùkò, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn. Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́, òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé. Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì, àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀. Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run. Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé, tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ. Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run, ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé, òun ni ó dá mànàmáná fún òjò, tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀; gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì, nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn; kò sí èémí ninu wọn. Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n; ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni. Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi, nítorí òun ló dá ohun gbogbo, Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀; OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀, ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi! Nítorí OLUWA wí pé, “Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò. N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.” Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́! Ọgbẹ́ náà sì pọ̀. Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé, “Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi, mo sì gbọdọ̀ fara dà á.” Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já. Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́. Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi. Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan, wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí, tí gbogbo agbo wọn sì fi túká. Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀! Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro yóo sì di ibùgbé àwọn ajáko. OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀. Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA, ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí, kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ, kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́, ni kí o bínú sí kí ó pọ̀, ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ; nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.

Jer 10:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLúWA sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. Báyìí ni OLúWA wí: “Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí, kí ààmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè. Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó kí ó má ba à ṣubú. Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko, òrìṣà wọn kò le è fọhùn. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé wọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣe bẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankan bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.” Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ OLúWA; o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára. Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ. Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè, wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi, àti wúrà láti Upasi; èyí tí àwọn oníṣọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà. Ṣùgbọ́n OLúWA ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀. “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèkéé tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ” Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀. Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkùùkuu ru sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀. Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀, ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀, nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni, kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀. Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà; nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé. Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì. Nítorí èyí ni OLúWA wí: “Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.” Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi! Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi, “Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.” Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já. Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́ Kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́, tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè, wọn kò sì wá OLúWA: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká. Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀, àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá! Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro, àti ihò ọ̀wàwà. Èmi mọ̀ OLúWA wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀. Tún mi ṣe OLúWA, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ, kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo. Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́n, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá, wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.