Jer 1:1-3
Jer 1:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini. Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀. O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun.
Jer 1:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí. Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀. Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà.
Jer 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.