A. Oni 8:1-3
A. Oni 8:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọkunrin Efraimu si wi fun u pe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa bayi, ti iwọ kò fi pè wa, nigbati iwọ nlọ bá awọn ara Midiani jà? Nwọn si bá a sọ̀ gidigidi. On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ? Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì.
A. Oni 8:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu. Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ. Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́.
A. Oni 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn àgbàgbà ẹ̀yà Efraimu sì bínú gidigidi sí Gideoni wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Midiani jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí? Ọlọ́run ti fi Orebu àti Seebu àwọn olórí àwọn ará Midiani lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Mose ṣe tí ó tó fiwé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín?” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọlẹ̀.