A. Oni 5:7-12
A. Oni 5:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn olori tán ni Israeli, nwọn tán, titi emi Debora fi dide, ti emi dide bi iya ni Israeli. Nwọn ti yàn ọlọrun titun; nigbana li ogun wà ni ibode: a ha ri asà tabi ọ̀kọ kan lãrin ẹgba ogún ni Israeli bi? Àiya mi fà si awọn alaṣẹ Israeli, awọn ti nwọn fi tinutinu wá ninu awọn enia: ẹ fi ibukún fun OLUWA. Ẹ sọ ọ, ẹnyin ti ngùn kẹtẹkẹtẹ funfun, ẹnyin ti njoko lori ẹni daradara, ati ẹnyin ti nrìn li ọ̀na. Li ọ̀na jijìn si ariwo awọn tafàtafa nibiti a gbé nfà omi, nibẹ̀ ni nwọn o gbé sọ iṣẹ ododo OLUWA, ani iṣẹ ododo ijọba rẹ̀ ni Israeli. Nigbana ni awọn enia OLUWA sọkalẹ lọ si ibode. Jí, jí, Debora; Jí, jí, kọ orin: dide, Baraki, ki o si ma kó awọn igbekun rẹ ni igbekun, iwọ ọmọ Abinoamu.
A. Oni 5:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá, gbogbo ìlú di àkọ̀tì, títí tí ìwọ Debora fi dìde, bí ìyá, ní Israẹli. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun, ogun bo gbogbo ẹnubodè. Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli, ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀? Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli, tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan. Ẹ fi ìyìn fún OLUWA. Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA, ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn. Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora! Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin! Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ, ìwọ ọmọ Abinoamu!
A. Oni 5:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn olórí tán ní Israẹli, wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde bí ìyá ní Israẹli. Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ẹgbàá ogun ní Israẹli bí. Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn Ẹ fi ìbùkún fún OLúWA! “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára, àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà, Ní ọ̀nà jíjìn sí ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi. Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo OLúWA, àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli. “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn OLúWA sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè. ‘Jí, jí, Debora! Jí, jí, kọ orin dìde! Dìde ìwọ Baraki! Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’