A. Oni 4:2-4
A. Oni 4:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède. Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi. Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na.
A. Oni 4:2-4 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún. Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà.
A. Oni 4:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà OLúWA jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe OLúWA fún ìrànlọ́wọ́. Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà.