A. Oni 3:7-30

A. Oni 3:7-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu. Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu. Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú. Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA. O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ. Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu. Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún. O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀. Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ. Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀. Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀. Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn: Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin. Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn. Nigbati o si jade lọ tán, awọn iranṣẹ rẹ̀ dé; nigbati nwọn wò, si kiyesi i, awọn ilẹkun gbọngan tì; nwọn wipe, Li aisí aniani o bò ẹsẹ̀ rẹ̀ ninu yará itura rẹ̀. Nwọn si duro titi o fi di itiju fun wọn: kiyesi i on kò si ṣí ilẹkun gbọngan na silẹ; nitorina nwọn mú ọmọlẹkun, nwọn si ṣí i: si kiyesi i, oluwa wọn ti ṣubu lulẹ kú. Ehudu si sálọ nigbati nwọn nduro, o si kọja ibi ere finfin, o si sálọ si Seira. O si ṣe, nigbati o dé, o fọn ipè ni ilẹ òke Efraimu, awọn ọmọ Israeli si bá a sọkalẹ lọ lati òke na wá, on si wà niwaju wọn. On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀. Nwọn si pa ìwọn ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ara Moabu ni ìgba na, gbogbo awọn ti o sigbọnlẹ, ati gbogbo awọn akọni ọkunrin; kò sí ọkunrin kanṣoṣo ti o sálà. Bẹ̃li a tẹ̀ ori Moabu ba ni ijọ́ na li abẹ ọwọ́ Israeli. Ilẹ na si simi li ọgọrin ọdún.

A. Oni 3:7-30 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, lágbára lórí wọn, nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Egiloni yìí kó àwọn ará Amoni ati àwọn ará Amaleki sòdí, wọ́n lọ ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, lọ́wọ́ wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sin Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, fún ọdún mejidinlogun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n tún ké pe OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan, ọlọ́wọ́ òsì, dìde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ehudu, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini. Ní àkókò kan àwọn ọmọ Israẹli fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Ehudu rọ idà olójú meji kan tí kò gùn ju igbọnwọ kan lọ, ó fi bọ inú àkọ̀, ó so ó mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún lábẹ́ aṣọ. Ó fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Egiloni yìí jẹ́ ẹni tí ó sanra rọ̀pọ̀tọ̀. Nígbà tí Ehudu fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tí wọ́n rù ú máa pada lọ. Òun nìkan bá pada ní ibi òkúta tí wọ́n gbẹ́, tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó tọ ọba lọ, ó ní, “Kabiyesi, mo ní iṣẹ́ àṣírí kan tí mo fẹ́ jẹ́ fún ọ.” Ọba bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn sì jáde. Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí. Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn. Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde. Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà. Lẹ́yìn tí ó ti sá lọ ni àwọn iranṣẹ ọba pada dé. Nígbà tí wọn rí i pé wọ́n ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n rò ninu ara wọn pé, bóyá ọba wà ninu ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó wà ninu yàrá orí òrùlé náà ni. Wọ́n dúró títí tí agara fi dá wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó kọ̀ tí kò ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n bá mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn; wọ́n bá bá òkú oluwa wọn nílẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn iranṣẹ wọnyi ń dúró pé kí ọba ṣílẹ̀kùn, Ehudu ti sá lọ, ó sì ti kọjá òkúta gbígbẹ́ tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó ti sá dé Seira. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. Wọ́n pa àwọn alágbára ati akikanju bí ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ará Moabu, kò sì sí ẹnìkan tí ó là ninu wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe ṣẹgun wọn ní ọjọ́ náà, ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ọgọrin ọdún.

A. Oni 3:7-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú OLúWA, wọ́n gbàgbé OLúWA Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah. Ìbínú OLúWA sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu (ìlà-oòrùn Siria) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí OLúWA, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀. Ẹ̀mí OLúWA bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. OLúWA sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú. Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú OLúWA, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, OLúWA fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli. Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ (Jeriko). Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjì-dínlógún. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe OLúWA, OLúWA rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu. Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún. Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀. Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnrarẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀. Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà. Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ. Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú. Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí OLúWA ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.