A. Oni 3:1-11

A. Oni 3:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani; Nitori idí yi pe, ki iran awọn ọmọ Israeli ki o le mọ̀, lati ma kọ́ wọn li ogun, ani irú awọn ti kò ti mọ̀ ọ niṣaju rí; Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati. Wọnyi li a o si ma fi dan Israeli wò, lati mọ̀ bi nwọn o fetisi ofin OLUWA, ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ́ Mose wá. Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi: Nwọn si fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn. Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu. Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu. Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú.

A. Oni 3:1-11 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani. Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati. Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi. Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí.

A. Oni 3:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí OLúWA fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun): Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin OLúWA, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose. Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú OLúWA, wọ́n gbàgbé OLúWA Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah. Ìbínú OLúWA sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu (ìlà-oòrùn Siria) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí OLúWA, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀. Ẹ̀mí OLúWA bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. OLúWA sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.