A. Oni 20:1-23

A. Oni 20:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa. Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà. (Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri? Ọkunrin Lefi na, bale obinrin na ti a pa, dahùn wipe, Mo wá si Gibea ti iṣe ti Benjamini, emi ati àle mi, lati wọ̀. Awọn ọkunrin Gibea si dide si mi, nwọn si yi ile na ká mọ́ mi li oru; nwọn si rò lati pa mi, nwọn si ba àle mi ṣe iṣekuṣe, o si kú. Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli. Kiyesi i, ọmọ Israeli ni gbogbo nyin ṣe, ẹ mú èro ati ìmọran nyin wá. Gbogbo awọn enia na si dide bi ọkunrin kan, wipe, Kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio wọ̀ inu agọ́ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni kò sí ẹnikẹni ti yio pada si ile rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi eyi li ohun ti a o ṣe si Gibea; awa ṣẹ keké, awa o si gòke lọ sibẹ̀; Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli. Bẹ̃ni gbogbo ọkunrin Israeli dó tì ilu na, nwọn fi ìmọ ṣọkan bi enia kan. Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi? Njẹ nisisiyi ẹ mu awọn ọkunrin na fun wa wá, awọn ọmọ Beliali, ti nwọn wà ni Gibea, ki awa ki o le pa wọn, ki awa ki o le mú ìwabuburu kuro ni Israeli. Ṣugbọn awọn ọmọ Benjamini kò fẹ́ fetisi ohùn awọn ọmọ Israeli awọn arakunrin wọn. Awọn ọmọ Benjamini si kó ara wọn jọ lati ilu wọnni wá si Gibea, lati jade lọ ibá awọn ọmọ Israeli jagun. A si kà awọn ọmọ Benjamini li ọjọ́ na, lati ilu wọnni wá, nwọn jẹ́ ẹgbã mẹtala ọkunrin ti nkọ idà, lẹhin awọn ara Gibea ti a kà, ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin. Ninu gbogbo awọn enia yi, a ri ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin aṣòsi; olukuluku wọn le gbọ̀n kànakana ba fọnrán owu li aitase. Ati awọn ọkunrin Israeli, li àika Benjamini, si jẹ́ ogún ọkẹ enia ti o nkọ idà: gbogbo awọn wọnyi si jẹ́ ologun. Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si lọ si Beti-eli nwọn si bère lọdọ Ọlọrun, wipe, Tani ninu wa ti yio tètekọ gòke lọ ibá awọn ọmọ Benjamini jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio tète gòke lọ. Awọn ọmọ Israeli si dide li owurọ̀, nwọn si dótì Gibea. Awọn ọkunrin Israeli si jade lọ ibá Benjamini jà; awọn ọkunrin Israeli si tẹ́gun dè wọn ni Gibea. Awọn ọmọ Benjamini si ti Gibea jade wá, nwọn si pa ẹgba mọkanla enia ninu awọn ọmọ Israeli. Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini. (Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.)

A. Oni 20:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa. Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000). Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa. Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?” Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀. Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú. Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli. Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.” Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀. Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea. Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.” Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà. Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí? Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí. Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ. Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé. Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini. OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea, wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn. Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn. Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?” OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

A. Oni 20:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú OLúWA ni Mispa. Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. (Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.” Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli. Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.” Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà. Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli. Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà. Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé). Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà. Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?” OLúWA dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.” Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah). Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah. Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá-mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú OLúWA títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ OLúWA. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?” OLúWA dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”