A. Oni 2:8-15

A. Oni 2:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ OLúWA, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110). Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi. Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin OLúWA nítorí wọn kò mọ OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú OLúWA, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. Wọ́n kọ OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú OLúWA bínú, nítorí tí wọ́n kọ̀ OLúWA sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli OLúWA fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí. Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ OLúWA sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.