A. Oni 2:6-13
A. Oni 2:6-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na. Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún. Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi. Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli. Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu: Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu. Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu.
A. Oni 2:6-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Joṣua tú àwọn ọmọ Israẹli ká, olukuluku wọn pada lọ sí orí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn eniyan náà sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n kù lẹ́yìn rẹ̀ wà láàyè, àwọn tí wọ́n fi ojú rí àwọn iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA, ṣaláìsí nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n sì sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní ìhà àríwá òkè Gaaṣi. Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu.
A. Oni 2:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn tí Joṣua ti tú àwọn ènìyàn Israẹli ká, àwọn ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn. Àwọn ènìyàn náà sin OLúWA ní gbogbo ìgbà ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Joṣua ọmọ Nuni, ìránṣẹ́ OLúWA, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110). Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Timnati-Hereki ní ilẹ̀ òkè Efraimu ní àríwá òkè Gaaṣi. Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin OLúWA nítorí wọn kò mọ OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú OLúWA, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. Wọ́n kọ OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú OLúWA bínú, nítorí tí wọ́n kọ̀ OLúWA sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti.