A. Oni 2:10-15
A. Oni 2:10-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli. Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu: Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu. Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn. Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀.
A. Oni 2:10-15 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n mọ OLUWA ati ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli patapata ni wọ́n kú, àwọn ìran mìíràn sì dìde lẹ́yìn wọn, wọn kò mọ OLUWA, ati gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ oriṣa Baali. Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n ń bọ oriṣa Baali ati Aṣitarotu. Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́. Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá jáde lọ láti jagun, OLUWA á kẹ̀yìn sí wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti kìlọ̀ fún wọn tí ó sì búra fún wọn, ìdààmú a sì dé bá wọn.
A. Oni 2:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin OLúWA nítorí wọn kò mọ OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú OLúWA, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali. Wọ́n kọ OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú OLúWA bínú, nítorí tí wọ́n kọ̀ OLúWA sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli OLúWA fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí. Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ OLúWA sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.