A. Oni 2:1-2
A. Oni 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ANGELI OLUWA si ti Gilgali gòke wá si Bokimu. O si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai: Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?
A. Oni 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli OLUWA gbéra láti Giligali, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní Bokimu, ó sọ fún wọn pé, “Mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá yín pé n óo fún wọn. Mo ní, ‘N kò ní yẹ majẹmu tí mo bá yín dá, ati pé, ẹ kò gbọdọ̀ bá èyíkéyìí ninu àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí dá majẹmu kankan, ẹ sì gbọdọ̀ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ kò mú àṣẹ tí mo pa fun yín ṣẹ. Irú kí ni ẹ dánwò yìí?
A. Oni 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan angẹli OLúWA dìde kúrò láti Gilgali lọ sí Bokimu ó sì wí pé, “Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, èmi sì síwájú yín wá sí ilẹ̀ tí mo ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín. Èmi sì wí pé, ‘Èmi kì yóò yẹ májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá àwọn ènìyàn ilẹ̀ yí dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò wó pẹpẹ ibi ìsin òrìṣà wọn lulẹ̀.’ Síbẹ̀ ẹ̀yin ṣe àìgbọ́ràn sí mi. Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?