A. Oni 17:5-6
A. Oni 17:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkunrin na Mika si ní ile-oriṣa kan, o si ṣe efodu, ati terafimu, o si yà ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sọtọ̀, ẹniti o si wa di alufa rẹ̀. Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.
Pín
Kà A. Oni 17A. Oni 17:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe.
Pín
Kà A. Oni 17A. Oni 17:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.
Pín
Kà A. Oni 17