A. Oni 17:1-13
A. Oni 17:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌKUNRIN kan si wà ni ilẹ òke Efraimu, orukọ ẹniti ijẹ Mika. On si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẹdẹgbẹfa owo fadakà ti a kólọ lọwọ rẹ, nitori eyiti iwọ gegún, ti iwọ si sọ̀rọ rẹ̀ li etí mi pẹlu, kiyesi i, fadakà na wà li ọwọ́ mi; emi li o kó o. Iya rẹ̀ si wipe, Alabukún ti OLUWA ni ọmọ mi. On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada. Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika. Ọkunrin na Mika si ní ile-oriṣa kan, o si ṣe efodu, ati terafimu, o si yà ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sọtọ̀, ẹniti o si wa di alufa rẹ̀. Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀. Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀. Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ. Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri. Mika si wi fun u pe, Bá mi joko, ki iwọ ki o ma ṣe baba ati alufa fun mi, emi o ma fi owo fadakà mẹwa fun ọ li ọdún, adápe aṣọ kan, ati onjẹ rẹ. Bẹ̃ni ọmọ Lefi na si wọle. O si rọ̀ ọmọ Lefi na lọrùn lati bá ọkunrin na joko; ọmọkunrin na si wà lọdọ rẹ̀ bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀. Mika si yà ọmọ Lefi na sọ̀tọ, ọmọkunrin na si wa di alufa rẹ̀, o si wà ninu ile Mika. Mika si wipe, Njẹ nisisiyi li emi tó mọ̀ pe, OLUWA yio ṣe mi li ore, nitoriti emi li ọmọ Lefi kan li alufa mi.
A. Oni 17:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.” Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀. Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.” Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika. Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe. Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀. Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?” Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.” Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.” Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ. Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika. Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.”
A. Oni 17:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.” Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí OLúWA bùkún ọ ọmọ mi!” Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí OLúWA fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.” Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba (200) ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika. Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, Ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu. Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.” Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé OLúWA yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”