A. Oni 14:1-20
A. Oni 14:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
SAMSONI si sọkalẹ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini. O si gòke wá, o si sọ fun baba on iya rẹ̀, o si wipe, Emi ri obinrin kan ni Timna ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini: njẹ nitorina ẹ fẹ́ ẹ fun mi li aya. Nigbana ni baba on iya rẹ̀ wi fun u pe, Kò sí obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakunrin rẹ, tabi ninu gbogbo awọn enia mi, ti iwọ fi nlọ ní obinrin ninu awọn alaikọlà Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ̀ pe, Fẹ́ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi. Ṣugbọn baba ati iya rẹ̀ kò mọ̀ pe ati ọwọ́ OLUWA wá ni, nitoripe on nwá ọ̀na lati bá awọn Filistini jà. Nitoripe li akokò na awọn Filistini li alaṣẹ ni Israeli. Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i. Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe. On si sọkalẹ lọ, o si bá obinrin na sọ̀rọ; on si wù Samsoni gidigidi. Lẹhin ijọ́ melokan o si tun pada lati mú obinrin na, o si yà lati wò okú kiniun na: si kiyesi i, ìṣu-ọ̀pọ oyin wà ninu okú kiniun na, ati oyin. O si bù ninu rẹ̀ si ọwọ́ rẹ̀, o si njẹ ẹ li ajẹrìn, titi o si fi dé ọdọ baba ati iya rẹ̀, o si fi fun wọn, nwọn si jẹ: ṣugbọn on kò sọ fun wọn pe ninu okú kiniun li on ti mú oyin na wá. Baba rẹ̀ si sọkalẹ tọ̀ obinrin na lọ: Samsoni si sè àse nibẹ̀; nitoripe bẹ̃li awọn ọmọkunrin ima ṣe. O si ṣe nigbati nwọn ri i, nwọn si mú ọgbọ̀n enia wa bá a kẹgbẹ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki npa alọ́ kan fun nyin: bi ẹnyin ba le já a fun mi titi ijọ́ meje àse yi, ti ẹnyin ba si mọ̀ ọ, njẹ emi o fun nyin li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ: Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba le já a fun mi, njẹ ẹnyin o fun mi li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ. Nwọn si wi fun u pe, Pa alọ́ rẹ ki awa ki o gbọ́. O si wi fun wọn pe, Lati inu ọjẹun li onjẹ ti jade wá, ati lati inu alagbara li adùn ti jade wá. Nwọn kò si le já alọ́ na nìwọn ijọ́ mẹta. O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn si wi fun obinrin Samsoni pe, Tàn ọkọ rẹ, ki o le já alọ́ na fun wa, ki awa ki o má ba fi iná sun iwọ ati ile baba rẹ: ẹnyin pè wa ki ẹnyin ki o le gbà ohun-iní wa ni? bẹ̃ ha kọ? Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi? O si sọkun niwaju rẹ̀ titi ijọ́ meje ti àse na gbà: O si ṣe ni ijọ́ keje, o si já a fun u, nitoripe on ṣe e li aisimi pupọ̀, on si já alọ́ na fun awọn ọmọ enia rẹ̀. Awọn ọkunrin ilunla na si wi fun u ni ijọ́ keje ki õrùn ki o to wọ̀ pe, Kili o dùn jù oyin lọ? kili o si lí agbara jù kiniun lọ? On si wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin kò fi ẹgbọrọ abo-malu mi tulẹ, ẹnyin kì ba ti mọ̀ alọ́ mi. Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀. Nwọn si fi obinrin Samsoni fun ọkan ninu awọn ẹgbẹ rẹ̀, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀.
A. Oni 14:1-20 Yoruba Bible (YCE)
Samsoni lọ sí Timna, ó rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia níbẹ̀. Ó pada wálé wá sọ fún baba ati ìyá rẹ̀, ó ní, “Mo rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia ní Timna, ó wù mí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fẹ́ ẹ fún mi.” Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?” Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.” Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí. Samsoni bá baba ati ìyá rẹ̀ lọ sí Timna ní ọjọ́ kan. Bí ó ti dé ibi ọgbà àjàrà àwọn ará Timna kan báyìí, ni ọ̀dọ́ kinniun kan bá bú mọ́ ọn. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì fún un ní agbára ńlá, ó bá fa kinniun náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí eniyan ya ọmọ ewúrẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ohunkohun lọ́wọ́. Ṣugbọn kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún baba tabi ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó lọ bá ọmọbinrin náà sọ̀rọ̀. Ọmọbinrin náà wù ú gidigidi. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni ó pada lọ láti lọ mú iyawo rẹ̀. Bí ó ti ń lọ, ó yà wo òkú kinniun tí ó pa, ó bá ọ̀wọ́ oyin ati afárá oyin lára rẹ̀. Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà. Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.” Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.” Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní, “Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá, láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.” Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?” Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ fún ọ?” Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé, “Kí ló dùn ju oyin lọ; kí ló lágbára ju kinniun lọ?” Ó ní, “Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀, ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.” Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu. Wọ́n bá fi iyawo rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àkókò igbeyawo.
A. Oni 14:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà kan Samsoni gòkè lọ sí Timna níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Filistini kan. Nígbà tí ó darí dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo rí obìnrin Filistini kan ní Timna: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi.” Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.” (Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ OLúWA ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Filistini jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Israẹli ní àkókò náà.) Samsoni sọ̀kalẹ̀ lọ sí Timna òun àti baba àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Timna, láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ̀mí OLúWA sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀. Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Samsoni sì yọ́ sí i. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin, ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà. Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Samsoni sì ṣe àsè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà. Nígbà tí ó fi ara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́. Samsoni sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtumọ̀ rẹ̀ láàrín ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àlọ́ náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpààrọ̀ aṣọ ìyàwó. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpààrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.” Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.” Ó dáhùn pé, “Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá; láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.” Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtumọ̀ sí àlọ́ náà. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Samsoni, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòṣì tàbí kó wa lẹ́rú ni?” Nígbà náà ni ìyàwó Samsoni ṣubú lé e láyà, ó sì sọkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! O kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” “Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.” Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?” Samsoni dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.” Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí OLúWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru. Wọ́n sì fi ìyàwó Samsoni fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.