A. Oni 13:5
A. Oni 13:5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.
Pín
Kà A. Oni 13A. Oni 13:5 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”
Pín
Kà A. Oni 13A. Oni 13:5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.”
Pín
Kà A. Oni 13