A. Oni 13:1-25

A. Oni 13:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún. Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ. Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan. Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini. Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi: Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀. Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi. Ọlọrun si gbọ ohùn Manoa; angeli Ọlọrun na si tun tọ̀ obinrin na wá, bi on ti joko ninu oko; ṣugbọn Manoa ọkọ rẹ̀ kò sí nibẹ̀ pẹlu rẹ̀. Obinrin na si yara kánkán, o si sure, o si sọ fun ọkọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Kiyesi i, ọkunrin ti o tọ̀ mi wá ni ijelo farahàn mi. Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni. Manoa si wipe, Njẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ: ìwa ọmọ na yio ti jẹ́, iṣẹ rẹ̀ yio ti jẹ́? Angeli OLUWA si wi fun Manoa pe, Ni gbogbo eyiti mo sọ fun obinrin na ni ki o kiyesi. Ki o má ṣe jẹ ohun kan ti o ti inu àjara wá, ki o má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ ohun aimọ́ kan; gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun u ni ki o kiyesi. Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o da ọ duro, titi awa o si fi pèse ọmọ ewurẹ kan fun ọ. Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe. Manoa si wi fun angeli OLUWA na pe, Orukọ rẹ, nitori nigbati ọ̀rọ rẹ ba ṣẹ ki awa ki o le bọlá fun ọ? Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi, kiyesi i, Iyanu ni. Manoa si mú ọmọ ewurẹ kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ, o si ru u lori apata kan si OLUWA: angeli na si ṣe ohun iyanu, Manoa ati obinrin rẹ̀ si nwò o. O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ. Ṣugbọn angeli OLUWA na kò si tun farahàn fun Manoa tabi aya rẹ̀ mọ́. Nigbana ni Manoa to wa mọ̀ pe, angeli OLUWA ni iṣe. Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun. Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi. Obinrin na si bi ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samsoni: ọmọ na si dàgba, OLUWA si bukún u. Ẹmi OLUWA si bẹ̀rẹsi ṣiṣẹ ninu rẹ̀ ni Mahane-dani, li agbedemeji Sora ati Eṣtaolu.

A. Oni 13:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún. Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.” Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.” Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. Obinrin náà bá sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ mi níjọ́sí tún ti fara hàn mí.” Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?” Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí. Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.” Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.” Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni. Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.” Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?” Manoa bá mú ọmọ ewúrẹ́ náà, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ó fi wọ́n rúbọ lórí òkúta kan sí OLUWA tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀. Angẹli OLUWA náà kò tún fara han Manoa ati iyawo rẹ̀ mọ́. Manoa wá mọ̀ nígbà náà pé, angẹli OLUWA ni. Manoa bá sọ fún iyawo rẹ̀ pé, “Dájúdájú, a óo kú, nítorí pé a ti rí Ọlọrun.” Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.” Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un. Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu.

A. Oni 13:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú OLúWA, OLúWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistini lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún. Ọkùnrin ará Sora kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Manoa láti ẹ̀yà Dani. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ. Angẹli OLúWA fi ara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tí ì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.” Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí OLúWA wí pé, “Háà OLúWA, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.” Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko: Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fi ara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.” Manoa yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkùnrin náà dáhùn pé “Èmi ni.” Manoa bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?” Angẹli OLúWA náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.” Manoa sọ fún angẹli OLúWA náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.” Angẹli OLúWA náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí OLúWA.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLúWA ní i ṣe.) Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli OLúWA náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” Ṣùgbọ́n angẹli OLúWA náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.” Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí OLúWA. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò OLúWA ṣe ohun ìyanu kan. Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli OLúWA gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀. Nígbà tí angẹli OLúWA náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli OLúWA ni. Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí OLúWA bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.” Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà OLúWA sì bùkún un. Ẹ̀mí OLúWA sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli.