A. Oni 11:1-40
A. Oni 11:1-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
JEFTA ara Gileadi si jẹ́ akọni ọkunrin, on si jẹ́ ọmọ panṣaga obinrin kan: Gileadi si bi Jefta. Aya Gileadi si bi awọn ọmọkunrin fun u; nigbati awọn ọmọ aya na si dàgba, nwọn si lé Jefta jade, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ki yio jogún ni ile baba wa; nitoripe ọmọ ajeji obinrin ni iwọ iṣe. Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ, O si ṣe lẹhin ijọ́ melokan, awọn ọmọ Ammoni bá Israeli jagun. O si ṣe nigbati awọn Ammoni bá Israeli jagun, awọn àgba Gileadi si lọ mú Jefta lati ilẹ Tobu wa. Nwọn si wi fun Jefta pe, Wá, jẹ́ olori wa, ki awa ki o le bá awọn ọmọ Ammoni jà. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Ẹnyin kò ha ti korira mi, ẹnyin kò ha ti lé mi kuro ni ile baba mi? ẽ si ti ṣe ti ẹnyin fi tọ̀ mi wá nisisiyi nigbati ẹnyin wà ninu ipọnju? Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Nitorina li awa ṣe pada tọ̀ ọ nisisiyi, ki iwọ ki o le bá wa lọ, ki o si bá awọn ọmọ Ammoni jà, ki o si jẹ́ olori wa ati ti gbogbo awọn ara Gileadi. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Bi ẹnyin ba mú mi pada lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti OLUWA ba si fi wọn fun mi, emi o ha jẹ́ olori nyin bi? Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Jẹ ki OLUWA ki o ṣe ẹlẹri lãrin wa, lõtọ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ bẹ̃li awa o ṣe. Nigbana ni Jefta bá awọn àgba Gileadi lọ, awọn enia na si fi i jẹ́ olori ati balogun wọn: Jefta si sọ gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ niwaju OLUWA ni Mispa. Jefta si rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni, wipe, Kili o ṣe temi tirẹ, ti iwọ fi tọ̀ mi wá, lati jà ni ilẹ mi? Ọba awọn ọmọ Ammoni si da awọn onṣẹ Jefta lohùn pe, Nitoriti Israeli ti gbà ilẹ mi, nigbati nwọn gòke ti Egipti wá, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati titi dé Jordani: njẹ́ nisisiyi fi ilẹ wọnni silẹ li alafia. Jefta si tun rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni: O si wi fun u pe, Bayi ni Jefta wi, Israeli kò gbà ilẹ Moabu, tabi ilẹ awọn ọmọ Ammoni: Ṣugbọn nigbati Israeli gòke ti Egipti wá, ti nwọn si nrìn li aginjù, titi dé Okun Pupa, ti nwọn si dé Kadeṣi; Nigbana ni Israeli rán onṣẹ si ọba Edomu, wipe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja ni ilẹ rẹ: ṣugbọn ọba Edomu kò gbọ́. Bẹ̃ gẹgẹ o si ranṣẹ si ọba Moabu pẹlu: ṣugbọn kò fẹ́: Israeli si joko ni Kadeṣi. Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu. Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn Amori, ọba Heṣboni; Israeli si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o kọja lãrin ilẹ rẹ si ipò mi. Ṣugbọn Sihoni kò gbẹkẹle Israeli lati kọja li àgbegbe rẹ̀: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo enia rẹ̀ jọ, nwọn si dó ni Jahasi, nwọn si bá Israeli jagun. OLUWA, Ọlọrun Israeli, si fi Sihoni, ati gbogbo enia rẹ̀ lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn: Israeli si gbà gbogbo ilẹ awọn Amori, awọn enia ilẹ na. Nwọn si gbà gbogbo àgbegbe awọn Amori, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati lati aginjù titi dé Jordani. Njẹ bẹ̃ni OLUWA, Ọlọrun Israeli, lé awọn Amori kuro niwaju Israeli awọn enia rẹ̀, iwọ o ha gbà a bi? Iwọ ki yio ha gbà eyiti Kemoṣu oriṣa rẹ fi fun ọ lati ní? Bẹ̃li ẹnikẹni ti OLUWA Ọlọrun wa ba lé kuro niwaju wa, ilẹ wọn ni awa o gbà. Njẹ iwọ ha san jù Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu? on ha bá Israeli ṣe gbolohùn asọ̀ rí, tabi o ha bá wọn jà rí? Nigbati Israeli fi joko ni Heṣboni ati awọn ilu rẹ̀, ati ni Aroeri ati awọn ilu rẹ̀, ati ni gbogbo awọn ilu ti o wà lọ titi de ẹba Arnoni, li ọdunrun ọdún; ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a li akokò na? Nitorina emi kò ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ li o ṣẹ̀ mi ni bibá mi jà: ki OLUWA, Onidajọ, ki o ṣe idajọ li oni lãrin awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Ammoni. Ṣugbọn ọba awọn ọmọ Ammoni kò fetisi ọ̀rọ Jefta, ti o rán si i. Nigbana li ẹmi OLUWA bà lé Jefta, on si kọja Gileadi ati Manasse, o si kọja Mispa ti Gileadi, ati lati Mispa ti Gileadi o si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni. Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ, Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun. Jefta si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni, lati bá wọn jà; OLUWA si fi nwọn lé e lọwọ. On si pa wọn ni ipakupa lati Aroeri lọ, titi dé atiwọ̀ Miniti, ani ogún ilu, titi o fi dé Abeli-kiramimu. Bẹ̃li a ṣẹgun awọn ọmọ Ammoni niwaju awọn ọmọ Israeli. Jefta si bọ̀ si ile rẹ̀ ni Mispa, si kiyesi i, ọmọbinrin rẹ̀ si jade wá ipade rẹ̀ ti on ti timbrili ati ijó: on nikan si li ọmọ rẹ̀; lẹhin rẹ̀ kò ní ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. O si ṣe nigbati o ri i, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Yẽ, ọmọ mi! iwọ rẹ̀ mi silẹ gidigidi, iwọ si li ọkan ninu awọn ti nyọ mi lẹnu: nitori emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada. On si wi fun u pe, Baba mi, iwọ ti yà ẹnu rẹ si OLUWA; ṣe si mi gẹgẹ bi eyiti o ti ẹnu rẹ jade; niwọnbi OLUWA ti gbẹsan fun ọ lara awọn ọtá rẹ, ani lara awọn ọmọ Ammoni. On si wi fun baba rẹ̀ pe, Jẹ ki a ṣe nkan yi fun mi: jọwọ mi jẹ li oṣù meji, ki emi ki o lọ ki emi si sọkalẹ sori òke, ki emi ki o le sọkun nitori ìwa-wundia mi, emi ati awọn ẹgbẹ mi. On si wipe, Lọ. O si rán a lọ niwọn oṣù meji: o si lọ, ati on ati awọn ẹgbẹ rẹ̀, o si sọkun nitori ìwa-wundia rẹ̀ lori òke wọnni. O si ṣe li opin oṣù keji, o si pada wá sọdọ baba rẹ̀, ẹniti o ṣe si i gẹgẹ bi ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́: on kò si mọ̀ ọkunrin. O si di ìlana ni Israeli pe, Ki awọn ọmọbinrin Israeli ma lọ li ọdọdún lati pohunrere ọmọbinrin Jefta ara Gileadi li ọjọ́ mẹrin li ọdún.
A. Oni 11:1-40 Yoruba Bible (YCE)
Jẹfuta ará Gileadi jẹ́ akikanju jagunjagun, ṣugbọn ọmọ aṣẹ́wó ni; Gileadi ni baba rẹ̀. Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.” Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri. Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu. Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.” Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?” Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.” Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?” Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” Jẹfuta bá àwọn àgbààgbà Gileadi pada lọ, àwọn ará Gileadi sì fi jẹ balogun wọn. Ó lọ siwaju OLUWA ní Misipa, ó sì sọ àdéhùn tí ó bá àwọn àgbààgbà Gileadi ṣe. Lẹ́yìn náà, Jẹfuta ranṣẹ sí ọba àwọn ará Amoni pé, “Kí ni mo ṣe tí o fi gbógun ti ilẹ̀ mi.” Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.” Jẹfuta tún ranṣẹ pada sí ọba Amoni pé, “Gbọ́ ohun tí èmi Jẹfuta wí, Israẹli kò gba ilẹ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn ará Moabu tabi lọ́wọ́ àwọn ará Amoni. Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi. Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà. Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’ Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà. Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni? Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú. Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí? Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà? Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.” Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni, nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.” Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láti Aroeri títí dé agbègbè Miniti tí ó fi wọ Abeli Keramimu. Àwọn ìlú tí ó run jẹ́ ogún. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣẹgun àwọn ará Amoni. Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí. Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.” Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.” Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.” Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin. Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá. Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli, pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun.
A. Oni 11:1-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jefta ará Gileadi jẹ́ akọni jagunjagun. Gileadi ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ panṣágà. Ìyàwó Gileadi sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jefta jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ panṣágà) ọmọ obìnrin mìíràn.” Jefta sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tobu, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ òfin lójú parapọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri. Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ammoni dìde ogun sí àwọn Israẹli, Ó sì ṣe nígbà tí àwọn Ammoni bá Israẹli jagun, àwọn àgbàgbà Gileadi tọ Jefta lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tobu. Wọ́n wí fún Jefta wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ammoni.” Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kórìíra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?” Àwọn àgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ammoni, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gileadi.” Jefta sì wí fún àwọn àgbàgbà Gileadi pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ammoni jà àti tí OLúWA bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́?” Àwọn àgbàgbà Gileadi sì wí fún Jefta pé, “Àwa fi OLúWA ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.” Jefta sì tẹ̀lé àwọn àgbàgbà Gileadi lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jefta sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ níwájú OLúWA ní Mispa. Jefta sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ammoni pé, “Kí ni ẹ̀sùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?” Ọba àwọn Ammoni dá àwọn oníṣẹ́ Jefta lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli jáde ti Ejibiti wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Arnoni dé Jabbok, àní dé Jordani, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.” Jefta sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ammoni ó sì wí fún un pé: “Báyìí ni Jefta wí: àwọn ọmọ Israẹli kò gba ilẹ̀ Moabu tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ammoni. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ejibiti àwọn ọmọ Israẹli la aginjù kọjá lọ sí ọ̀nà Òkun pupa wọ́n sì lọ sí Kadeṣi. Nígbà náà Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Edomu pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Edomu kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Moabu bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Israẹli dúró sí Kadeṣi. “Wọ́n rin aginjù kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Edomu àti ti Moabu sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà-oòrùn Moabu, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Arnoni. Wọn kò wọ ilẹ̀ Moabu, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Arnoni wà. “Nígbà náà ni Israẹli rán àwọn oníṣẹ́ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Heṣboni, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí ibùgbé wa.’ Ṣùgbọ́n Sihoni kò gba Israẹli gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jahisa láti bá Israẹli jagun. “OLúWA Ọlọ́run Israẹli sì fi Sihoni àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Israẹli sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé ní agbègbè náà, wọ́n gbà gbogbo agbègbè àwọn ará Amori, láti Arnoni tí ó fi dé Jabbok, àti láti aginjù dé Jordani. “Wàyí o, nígbà tí OLúWA Ọlọ́run Israẹli, ti lé àwọn ará Amori kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Israẹli, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kemoṣi òrìṣà rẹ fi fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí OLúWA Ọlọ́run wa fi fún wa. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Israẹli bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí? Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà? Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí OLúWA olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàrín àwọn ọmọ Israẹli àti àwọn ará Ammoni.” Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ammoni kò fetí sí iṣẹ́ tí Jefta rán sí i. Ẹ̀mí OLúWA sì bà lé Jefta òun sì la Gileadi àti Manase kọjá. Ó la Mispa àti Gileadi kọjá láti ibẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti bá àwọn ará Ammoni jà. Jefta sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ammoni lé mi lọ́wọ́, Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ó bá jáde láti ẹnu-ọ̀nà ilé mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ammoni ní àlàáfíà, yóò jẹ́ ti OLúWA, èmi yóò sì fi rú ẹbọ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” Jefta sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ammoni jagun, OLúWA sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́. Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní à pa tán láti Aroeri títí dé agbègbè Minniti, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Keramimu. Báyìí ni Israẹli ti ṣẹ́gun àwọn ará Ammoni. Nígbà tí Jefta padà sí ilé rẹ̀ ní Mispa, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú timbrili àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan. Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí OLúWA ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le sẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.” Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí OLúWA ti gba ẹ̀san fún ọ lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ará Ammoni. Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.” Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó. Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrín ọdún àwọn obìnrin Israẹli a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jefta ti Gileadi.