A. Oni 10:6-16
A. Oni 10:6-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu, ati Aṣtarotu, ati awọn oriṣa Siria, ati awọn oriṣa Sidoni, ati awọn oriṣa Moabu, ati awọn oriṣa awọn ọmọ Ammoni, ati awọn oriṣa awọn Filistini; nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn kò si sìn i. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ awọn ọmọ Ammoni. Li ọdún na nwọn ni awọn ọmọ Israeli lara, nwọn si pọ́n wọn loju: ọdún mejidilogun ni nwọn fi ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o wà ni ìha keji Jordani ni ilẹ awọn Amori, ti o wà ni Gileadi, lara. Awọn ọmọ Ammoni si gòke odò Jordani lati bá Juda jà pẹlu, ati Benjamini, ati ile Efraimu; a si ni Israeli lara gidigidi. Awọn ọmọ Israeli si kepè OLUWA wipe, Awa ti ṣẹ̀ si ọ, nitoriti awa ti kọ̀ Ọlọrun wa silẹ, a si nsín Baalimu. OLUWA si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi kò ti gbà nyin kuro lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ awọn ọmọ Amori, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini? Awọn ara Sidoni pẹlu, ati awọn Amaleki, ati awọn Maoni si ti npọ́n nyin loju; ẹnyin kepè mi, emi si gbà nyin lọwọ wọn. Ṣugbọn ẹnyin kọ̀ mi silẹ, ẹ si nsìn ọlọrun miran: nitorina emi ki yio tun gbà nyin mọ́. Ẹ lọ kigbepè awọn oriṣa ti ẹnyin ti yàn; jẹ ki nwọn ki o gbà nyin li akokò wahalà nyin. Awọn ọmọ Israeli si wi fun OLUWA pe, Awa ti ṣẹ̀: ohunkohun ti o ba tọ́ li oju rẹ ni ki o fi wa ṣe; sá gbà wa li oni yi, awa bẹ̀ ọ. Nwọn si kó ajeji ọlọrun wọnni ti o wà lọdọ wọn kuro, nwọn si nsìn OLUWA: ọkàn rẹ̀ kò si gbà òṣi Israeli mọ́.
A. Oni 10:6-16 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́. Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́. Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni. Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.” OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia. Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn. Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́. Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.” Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.” Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.
A. Oni 10:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú lójú OLúWA. Wọ́n sin Baali àti Aṣtoreti àti àwọn òrìṣà Aramu, òrìṣà Sidoni, òrìṣà Moabu, òrìṣà àwọn ará Ammoni àti òrìṣà àwọn ará Filistini. Nítorí àwọn ará Israẹli kọ OLúWA sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn ín mọ́, ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Filistini àti Ammoni láti jẹ ẹ́ ní ìyà. Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjì-dínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní ìlà-oòrùn odò Jordani ní ilẹ̀ àwọn ará Amori lára (èyí nì ní Gileadi). Àwọn ará Ammoni sì la odò Jordani kọjá láti bá Juda, Benjamini àti àwọn ará ilé Efraimu jagun: Israẹli sì dojúkọ ìpọ́njú tó lágbára. Nígbà tí èyí ti ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ké pe OLúWA wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ, nítorí pé àwa ti kọ Ọlọ́run wa sílẹ̀, àwa sì ń sin Baali.” OLúWA sì dáhùn pé, “Ǹjẹ́ nígbà tí àwọn ará Ejibiti, Amori, Ammoni, Filistini, àwọn ará Sidoni, Amaleki pẹ̀lú Maoni ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn? Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin kọ̀ mí sílẹ̀ láti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, torí ìdí èyí, èmi kì yóò sì tún gbà yín mọ́. Ẹ lọ kí ẹ sì ké pe àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ti yàn fún ara yín. Jẹ́ kí wọn gbà yín sílẹ̀ ní àsìkò ìpọ́njú yín!” Àwọn ọmọ Israẹli sì dá OLúWA lóhùn pé, “Àwa ti ṣẹ̀, ṣe ohun tí ó bá fẹ́ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n, jọ̀wọ́ gbà wá sílẹ̀ nání àsìkò yìí.” Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàrín wọn kúrò wọ́n sì sin OLúWA nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Israẹli mọ́.