A. Oni 10:17-18
A. Oni 10:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni awọn ọmọ Ammoni kó ara wọn jọ nwọn si dó si Gileadi. Awọn ọmọ Israeli si kó ara wọn jọ, nwọn si dó si Mispa. Awọn enia na, awọn olori Gileadi si wi fun ara wọn pe, ọkunrin wo ni yio bẹ̀rẹsi bá awọn ọmọ Ammoni jà? on na ni yio ṣe olori gbogbo awọn ara Gileadi.
A. Oni 10:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa. Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.”
A. Oni 10:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí àwọn ará Ammoni kógun jọ ní Gileadi láti bá Israẹli jà, àwọn ọmọ Israẹli gbárajọpọ̀, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Mispa. Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gileadi wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ ṣígun si àwọn ará Ammoni ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gileadi.”