A. Oni 10:1-5
A. Oni 10:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN Abimeleki li ẹnikan si dide lati gbà Israeli là, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, ọkunrin Issakari kan; o si ngbé Ṣamiri li òke Efraimu. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹtalelogun o si kú, a si sin i ni Ṣamiri. Lẹhin rẹ̀ ni Jairi dide, ara Gileadi; o si ṣe idajọ Israeli li ọdún mejilelogun. On si ní ọgbọ̀n ọmọkunrin ti ngùn ọgbọ̀n ọmọ kẹtẹkẹtẹ, nwọn si ní ọgbọ̀n ilu ti a npè ni Haffoti-jairi titi o fi di oni, eyiti o wà ni ilẹ Gileadi. Jairi si kú, a si sin i ni Kamoni.
A. Oni 10:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri. Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun. Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni.
A. Oni 10:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ikú Abimeleki, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Isakari tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, dìde láti gba Israẹli sílẹ̀. Ní Ṣamiri tí ó wà ní òkè Efraimu ni ó gbé. Ó ṣe àkóso Israẹli ní ọdún mẹ́tàlélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Ṣamiri. Jairi ti ẹ̀yà Gileadi ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Israẹli ní ọdún méjìlélógún. Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó n gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gileadi, tí a pe orúkọ wọn ní Hafoti-Jairi títí di òní. Nígbà tí Jairi kú wọ́n sin ín sí Kamoni.