A. Oni 1:9 - Compare All Versions

A. Oni 1:9 YBCV (Bibeli Mimọ)

Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì.

A. Oni 1:9 YCE (Yoruba Bible)

Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu.

A. Oni 1:9 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun.