A. Oni 1:29-30
A. Oni 1:29-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Efraimu kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn ni Geseri. Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahalolu; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si nsìn.
A. Oni 1:29-30 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́.
A. Oni 1:29-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni.