A. Oni 1:22-26
A. Oni 1:22-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn. Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.) Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ. O si fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jọwọ ọkunrin na ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀ lọwọ lọ. Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn Hitti, o si tẹ̀ ilu kan dó, o si pè orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyi si li orukọ rẹ̀ titi di oni.
A. Oni 1:22-26 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn. Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.) Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.” Ọkunrin náà bá fi ọ̀nà tí wọn ń gbà wọ ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n bá fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà, ṣugbọn wọ́n jẹ́ kí ọkunrin náà ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde lọ. Ọkunrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó tẹ ìlú kan dó, ó sì sọ ọ́ ní Lusi. Orúkọ náà ni wọ́n ń pe ìlú náà títí di òní olónìí.
A. Oni 1:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, OLúWA síwájú pẹ̀lú wọn. Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.