A. Oni 1:1-36

A. Oni 1:1-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọdọ OLUWA wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani lọ fun wa, lati bá wọn jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ. Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ. Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki. Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi. Ṣugbọn Adoni-beseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si mú u, nwọn si ke àtampako ọwọ́ rẹ̀, ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀. Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na. Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì. Juda si tọ̀ awọn ara Kenaani ti ngbé Hebroni lọ: (orukọ Hebroni ni ìgba iṣaju si ni Kiriati-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai. Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.) Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́? On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u. Awọn ọmọ Keni, ana Mose, si bá awọn ọmọ Juda gòke lati ilu ọpẹ lọ si aginjù Juda, ni gusù Aradi; nwọn si lọ, nwọn si mbá awọn enia na gbé. Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma. Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀. OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin. Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀. Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni. Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn. Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.) Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ. O si fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jọwọ ọkunrin na ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀ lọwọ lọ. Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn Hitti, o si tẹ̀ ilu kan dó, o si pè orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyi si li orukọ rẹ̀ titi di oni. Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na. O si ṣe, nigbati Israeli di alagbara tán, nwọn si mu awọn ara Kenaani sìn, nwọn kò si lé wọn jade patapata. Efraimu kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn ni Geseri. Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahalolu; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si nsìn. Aṣeri kò lé awọn ara Akko jade, tabi awọn ara Sidoni, tabi awọn ara Alabu, tabi awọn ara Aksibu, tabi awọn ara Helba, tabi awọn ara Afiki, tabi awọn ara Rehobu: Ṣugbọn awọn ọmọ Aṣeri ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: nitoriti nwọn kò lé wọn jade. Naftali kò lé awọn ara Beti-ṣemeṣi jade, tabi awọn ara Beti-anati; ṣugbọn on ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Beti-ṣemeṣi ati Beti-anati di ẹniti nsìn wọn. Awọn Amori si fi agbara tì awọn ọmọ Dani sori òke: nitoripe nwọn kò jẹ ki nwọn ki o sọkalẹ wá si afonifoji. Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn. Àla awọn Amori si ni lati ìgoke lọ si Akrabbimu, lati ibi apata lọ si òke.

A. Oni 1:1-36 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ikú Joṣua, àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ẹ̀yà wo ni kí ó kọ́kọ́ gbógun ti àwọn ará Kenaani?” OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yà Juda ni kí ó kọ́ dojú kọ wọ́n, nítorí pé, mo ti fi ilẹ̀ náà lé wọn lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn. Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki. Wọ́n bá Adonibeseki ní Beseki, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì ṣẹgun àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji. Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí. Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu. Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai. Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.) Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya. Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?” Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀. Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀. Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima. Àwọn ọmọ Juda ṣẹgun ìlú Gasa ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀. Wọ́n ṣẹgun ìlú Aṣikeloni ati Ekironi ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn. OLUWA wà pẹlu àwọn ọmọ Juda, ọwọ́ wọn tẹ àwọn ìlú olókè, ṣugbọn apá wọn kò ká àwọn tí ó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹtẹẹta kúrò níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò lé àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jáde; láti ìgbà náà ni àwọn ará Jebusi ti ń bá àwọn ọmọ Bẹnjamini gbé ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn. Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.) Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.” Ọkunrin náà bá fi ọ̀nà tí wọn ń gbà wọ ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n bá fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà, ṣugbọn wọ́n jẹ́ kí ọkunrin náà ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde lọ. Ọkunrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó tẹ ìlú kan dó, ó sì sọ ọ́ ní Lusi. Orúkọ náà ni wọ́n ń pe ìlú náà títí di òní olónìí. Àwọn ọmọ Manase kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ará Taanaki jáde, ati àwọn ará Dori, àwọn ará Ibileamu, àwọn ará Megido ati àwọn tí wọn ń gbé gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú náà; ṣugbọn àwọn ará Kenaani ṣì ń gbé ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára sí i, wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará Kenaani ṣiṣẹ́, ṣugbọn wọn kò lé wọn kúrò láàrin wọn patapata. Àwọn ọmọ Efuraimu kò lé àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Geseri jáde, wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa gbé ààrin wọn. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. Àwọn ọmọ Aṣeri náà kò lé àwọn wọnyi jáde: àwọn ará Ako ati àwọn ará Sidoni, àwọn ará Ahilabu ati àwọn ará Akisibu, àwọn ará Heliba ati àwọn ará Afeki, ati àwọn ará Rehobu. Ṣugbọn àwọn ọmọ Aṣeri ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani tí wọ́n bá ní ilẹ̀ náà, nítorí pé wọn kò lé wọn jáde. Àwọn ará Nafutali kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati àwọn ará Betanati jáde, ṣugbọn wọ́n ń gbé ààrin àwọn tí wọ́n bá ni ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati ti Betanati ṣiṣẹ́. Àwọn ará Amori ń lé àwọn ọmọ Dani sẹ́yìn sí àwọn agbègbè olókè, nítorí pé wọn kò fẹ́ gba àwọn ọmọ Dani láàyè rárá láti sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn ará Amori kọ̀, wọn kò jáde ní òkè Heresi, Aijaloni ati Ṣaalibimu, ṣugbọn àwọn ọmọ Josẹfu kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ títí tí àwọn ọmọ Josẹfu fi bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́. Ààlà àwọn ará Amori bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ̀ òkè Akirabimu, láti Sela lọ sókè.

A. Oni 1:1-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ikú Joṣua, ni orílẹ̀-èdè Israẹli béèrè lọ́wọ́ OLúWA pé “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kenaani jagun fún wa?” OLúWA sì dáhùn pé, “Juda ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.” Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, OLúWA sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Beseki. Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi. Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀. Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?” Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀. Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà. Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun). Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká. OLúWA sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin. Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní. Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, OLúWA síwájú pẹ̀lú wọn. Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní. Ṣùgbọ́n Manase kò lé àwọn ará Beti-Ṣeani àti ìlú rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jáde, tàbí àwọn ará Taanaki àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Dori àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Ibleamu àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Megido àti àwọn ìgbèríko tí ó yí i ká, torí pé àwọn ará Kenaani ti pinnu láti máa gbé ìlú náà. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn. Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.