Jak 5:7-12
Jak 5:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo. Ẹnyin pẹlu ẹ mu sũru; ẹ fi ọkàn nyin balẹ̀: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ. Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun. Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru. Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu. Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.
Jak 5:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé. Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa. Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́.
Jak 5:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn. Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú. Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.