Jak 5:1-11

Jak 5:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀. Ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa ké gidi nítorí ìṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣẹ́ yín. Ọrọ̀ yín ti bàjẹ́. Kòkòrò ti jẹ gbogbo aṣọ yín. Wúrà yín ati fadaka yín ti dógùn-ún. Dídógùn-ún wọn ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fun yín, nítorí yóo jẹ ara yín bí ìgbà tí iná bá ń jó nǹkan. Inú ayé tí ó fẹ́rẹ̀ dópin ni ẹ̀ ń to ìṣúra jọ sí! Owó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní oko yín, tí ẹ kò san fún wọn ń pariwo yín. Igbe àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ba yín kórè oko yín sì ti dé etí Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹ̀ ń ṣe fàájì ninu ayé, ẹ̀ ń jẹ, ẹ̀ ń mu. Ẹ wá sanra bíi mààlúù, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ tí wọn yóo dumbu mààlúù ló kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí. Ẹ gbé ẹ̀bi fún aláre, ẹ sì pa á, kò lè rú pútú. Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin gan-an mú sùúrù. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, nítorí Oluwa fẹ́rẹ̀ dé. Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà. Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa.

Jak 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín. Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn. Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.