Jak 4:6,8-10
Jak 4:6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn.
Jak 4:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji. Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu. Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.
Jak 4:6 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
JAKỌBU 4:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga.
Jak 4:6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
Jakọbu 4:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.