Jak 4:4-10
Jak 4:4-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun. Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa? Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn. Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin. Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji. Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu. Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.
Jak 4:4-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun. Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?” Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga.
Jak 4:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.” Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.