Jak 4:2-4
Jak 4:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère. Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin. Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.
Jak 4:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun. Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín. Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.
Jak 4:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní: ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín. Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run.