Jak 4:10-11
Jak 4:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga. Ará, ẹ máṣe sọ̀rọ ibi si ara nyin. Ẹniti o ba nsọ̀rọ ibi si arakunrin rẹ̀, ti o si ndá arakunrin rẹ̀ lẹjọ, o nsọ̀rọ ibi si ofin, o si ndá ofin lẹjọ; ṣugbọn bi iwọ ba ndá ofin lẹjọ, iwọ kì iṣe oluṣe ofin, bikoṣe onidajọ.
Jak 4:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga. Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí.
Jak 4:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga. Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.