Jak 3:7-8
Jak 3:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori olukuluku ẹda ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ejò, ati ti ohun ti mbẹ li okun, li a ntù loju, ti a si ti tù loju lati ọwọ ẹda enia wá. Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni.
Pín
Kà Jak 3Jak 3:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá.
Pín
Kà Jak 3Jak 3:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni.
Pín
Kà Jak 3