Jak 3:3-5
Jak 3:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi a bá si fi ijanu bọ̀ ẹṣin li ẹnu, ki nwọn ki o le gbọ́ ti wa, gbogbo ara wọn li awa si nyi kiri pẹlu. Kiyesi awọn ọkọ̀ pẹlu, bi nwọn ti tobi to nì, ti a si nti ọwọ ẹfũfu lile gbá kiri, itọkọ̀ kekere li a fi ndari wọn kiri, sibikibi ti o bá wù ẹniti ntọ́ ọkọ̀. Bẹ̃ pẹlu li ahọn jẹ ẹ̀ya kekere, o si nfọnnu ohun nla. Wo igi nla ti iná kekere nsun jóna!
Jak 3:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀. Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá!
Jak 3:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná!