Jak 3:13-16
Jak 3:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn. Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ. Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni. Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà.
Jak 3:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn. Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀.
Jak 3:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.