Jak 2:3-7
Jak 2:3-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ti ẹnyin si bu iyìn fun ẹniti o wọ̀ aṣọ daradara, ti ẹ si wipe, Iwọ joko nihinyi ni ibi daradara; ti ẹ si wi fun talakà na pe, Iwọ duro nibẹ̀, tabi joko nihin labẹ apoti itisẹ mi: Ẹnyin kò ha nda ara nyin si meji ninu ara nyin, ẹ kò ha si di onidajọ ti o ni ero buburu? Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ? Ṣugbọn ẹnyin ti bù talakà kù. Awọn ọlọrọ̀ kò ha npọ́n nyin loju, nwọn kò ha si nwọ́ nyin lọ si ile ẹjọ? Nwọn kò ha nsọ ọrọ-odi si orukọ rere nì ti a fi npè nyin?
Jak 2:3-7 Yoruba Bible (YCE)
ẹ óo máa fi ojurere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídán, ẹ óo sọ fún un pé, “Wá jókòó níbi dáradára yìí.” Ṣugbọn ẹ óo wá sọ fún talaka pé, “Dúró níbẹ̀, tabi wá jókòó nílẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ mi níhìn-ín.” Ǹjẹ́ ẹ kò fi bẹ́ẹ̀ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ara yín, ǹjẹ́ ẹ kò sì máa ṣe ìdájọ́ pẹlu èrò burúkú. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́. Ọlọrun ti yan àwọn mẹ̀kúnnù ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu igbagbọ ati láti jogún ìjọba tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀ ń kẹ́gàn mẹ̀kúnnù. Ṣebí àwọn ọlọ́rọ̀ níí máa fìtínà yín, tí wọn máa ń fà yín lọ sí kóòtù! Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín!
Jak 2:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára,” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí? Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?