Jak 2:20-24
Jak 2:20-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni? Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ? Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan.
Jak 2:20-24 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ? O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan?
Jak 2:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.