Jak 2:18-26
Jak 2:18-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi. Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri. Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni? Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ? Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan. Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran? Nitori bi ara li aisi ẹmí ti jẹ́ okú, bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni igbagbọ́ li aisi iṣẹ jẹ́ okú.
Jak 2:18-26 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ẹnìkan lè sọ pé, “Ìwọ ní igbagbọ, èmi ní iṣẹ́.” Fi igbagbọ rẹ hàn mí láìsí iṣẹ́, èmi óo fi igbagbọ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ní ń bẹ. Ó dára bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rùbojo sì mú wọn. Ìwọ eniyan lásán! O fẹ́ ẹ̀rí pé igbagbọ ti kò ní iṣẹ́ ninu jẹ́ òkú? Nípa iṣẹ́ kọ́ ni Abrahamu baba wa fi gba ìdáláre, nígbà tí ó fa Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ sí orí pẹpẹ ìrúbọ? O rí i pé igbagbọ ń farahàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, ati pé iṣẹ́ rẹ̀ ni ó ṣe igbagbọ rẹ̀ ní àṣepé. Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Ṣé ẹ wá rí i pé nípa iṣẹ́ ni eniyan fi ń gba ìdáláre, kì í ṣe nípa igbagbọ nìkan? Ṣebí bákan náà ni Rahabu aṣẹ́wó gba ìdáláre nípa iṣẹ́, nígbà tí ó ṣe àwọn amí ní àlejò, tí ó jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀nà mìíràn pada lọ? Bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ ni igbagbọ láìsí iṣẹ́.
Jak 2:18-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:” Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì. Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.