Jak 2:13-17
Jak 2:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ. Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi? Bi arakunrin tabi arabinrin kan ba wà ni ìhoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ, Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ? Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara.
Jak 2:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́. Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là? Bí arakunrin kan tabi arabinrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí kò jẹun fún odidi ọjọ́ kan, tí ẹnìkan ninu yín wá sọ fún un pé, “Máa lọ ní alaafia, Ọlọrun yóo pèsè aṣọ ati oúnjẹ fún ọ,” ṣugbọn tí kò fún olúwarẹ̀ ní ohun tí ó nílò, anfaani wo ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ ṣe? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni.
Jak 2:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́. Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.