Jak 1:21-26
Jak 1:21-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là. Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ. Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji: Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri. Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀. Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni.
Jak 1:21-26 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ ìyìn rere ṣe ìwà hù; ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán. Bí ẹ bá ń gbọ́ lásán, ara yín ni ẹ̀ ń tàn jẹ. Nítorí bí eniyan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí kò fi ṣe ìwà hù, olúwarẹ̀ dàbí ẹni tí ó wo ojú ara rẹ̀ ninu dígí. Ó wo ara rẹ̀ dáradára, ó kúrò níbẹ̀, kíá ó ti gbàgbé bí ojú rẹ̀ ti rí. Ṣugbọn ẹni tí ó bá wo òfin tí ó pé, tíí ṣe orísun òmìnira, tí ó sì dúró lé e lórí, olúwarẹ̀ kì í ṣe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó gbàgbé rẹ̀, ṣugbọn ó ń fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ìwà hù. Olúwarẹ̀ di ẹni ibukun nítorí ó ń fi ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ ṣe ìwà hù. Bí ẹnìkan bá rò pé òun jẹ́ olùfọkànsìn, tí kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni, asán sì ni ẹ̀sìn rẹ̀.
Jak 1:21-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán.