Jak 1:2-4
Jak 1:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba bọ́ sinu onirũru idanwò, ẹ kà gbogbo rẹ̀ si ayọ; Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru. Ṣugbọn ẹ jẹ ki sũru ki o ṣe iṣẹ aṣepé, ki ẹnyin ki o le jẹ pipe ati ailabuku, ki o má kù ohun kan fun ẹnikẹni.
Pín
Kà Jak 1Jak 1:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà. Ẹ níláti ní ìfaradà títí dé òpin, kí ẹ lè di pípé, kí ẹ sì ní ohun gbogbo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láìsí ìkùnà kankan.
Pín
Kà Jak 1Jak 1:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.
Pín
Kà Jak 1