Jak 1:18-20
Jak 1:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀. Ẹnyin mọ eyi, ẹnyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku enia ki o mã yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu: Nitori ibinu enia kì iṣiṣẹ ododo Ọlọrun.
Jak 1:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kí ẹ mọ nǹkankan: eniyan níláti tètè gbọ́ ọ̀rọ̀, ṣugbọn kí ó lọ́ra láti désì pada, kí ó sì lọ́ra láti bínú. Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́.
Jak 1:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá. Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.