Isa 9:1-3
Isa 9:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède. Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si. Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun.
Isa 9:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé. Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.
Isa 9:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani. Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá; Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú, ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí. Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá; wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀ nígbà tí à ń pín ìkógun.