Isa 7:13-25

Isa 7:13-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

On si wipe, Ẹ gbọ́ nisisiyi ẹnyin ara ile Dafidi, iṣe ohun kekere fun nyin lati dá enia lagara, ṣugbọn ẹnyin o ha si dá Ọlọrun mi lagara pẹlu bi? Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli. Ori-amọ ati oyin ni yio ma jẹ, ki o le ba mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire. Nitoripe, ki ọmọ na ki o to mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire, ilẹ ti iwọ korira yio di ikọ̀silẹ lọdọ ọba rẹ̀ mejeji. Oluwa yio si mu ọjọ ti kò si bẹ̃ ri wá sori rẹ ati sori awọn enia rẹ, ati sori ile baba rẹ, lati ọjọ ti Efraimu ti lọ kuro lọdọ Juda, ani ọba Assiria. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio kọ si eṣinṣin ti o wà li apa ipẹkun odo ṣiṣàn nlanla Egipti, ati si oyin ti o wà ni ilẹ Assiria. Nwọn o si wá, gbogbo wọn o si bà sinu afonifojì ijù, ati sinu pàlapala okuta, ati lori gbogbo ẹgun, ati lori eweko gbogbo. Li ọjọ kanna ni Oluwa yio fi abẹ ti a yá, eyini ni, awọn ti ihà keji odo nì, ọba Assiria, fá ori ati irun ẹsẹ, yio si run irungbọn pẹlu. Yio si ṣe li ọjọ na, enia kan yio si tọ́ ọmọ malu kan ati agutan meji; Yio si ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ wàra ti nwọn o mu wá, yio ma jẹ ori-amọ; nitori ori-amọ ati oyin ni olukulùku ti o ba kù ni ãrin ilẹ na yio ma jẹ. Yio si ṣe li ọjọ na, ibi gbogbo yio ri bayi pe, ibi ti ẹgbẹrun àjara ti wà fun ẹgbẹrun owo fadakà yio di ti ẹwọn ati ẹgun. Pẹlu ọfà ati ọrun ni enia yio wá ibẹ, nitoripe gbogbo ilẹ na yio di ẹwọn ati ẹgun. Ati lori gbogbo okè kékèké ti a o fi ọkọ́ tu, ẹ̀ru ẹ̀wọn ati ẹ̀gun ki yio de ibẹ̀: ṣugbọn yio jẹ ilu ti a ndà malũ lọ, ati ibi itẹ̀mọlẹ fun awọn ẹran kékèké.

Isa 7:13-25 Yoruba Bible (YCE)

Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli. Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ. Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀. “OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀. “Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria. Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá. “Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá. “Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré, wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ. “Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.”

Isa 7:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní ààmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli. Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere. Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro. OLúWA yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.” Ní ọjọ́ náà ni OLúWA yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria. Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú. Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin. Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà. Àti ní orí àwọn òkè kéékèèkéé tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèkéé.

Isa 7:13-25

Isa 7:13-25 YBCVIsa 7:13-25 YBCVIsa 7:13-25 YBCV