Isa 7:13-14
Isa 7:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wipe, Ẹ gbọ́ nisisiyi ẹnyin ara ile Dafidi, iṣe ohun kekere fun nyin lati dá enia lagara, ṣugbọn ẹnyin o ha si dá Ọlọrun mi lagara pẹlu bi? Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli.
Isa 7:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Aisaya bá dáhùn pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Dafidi, ṣé eniyan tí ẹ̀ ń yọ lẹ́nu kò to yín, Ọlọrun mi alára lókù tí ẹ tún ń yọ lẹ́nu? Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.
Isa 7:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní ààmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.