Isa 66:7-11
Isa 66:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki o to rọbi, o bimọ; ki irora rẹ̀ ki o to de, o bi ọmọkunrin kan. Tali o ti igbọ́ iru eyi ri? tali o ti iri irú eyi ri? Ilẹ le hù nkan jade li ọjọ kan bi? tabi a ha le bi orilẹ-ède ni ọjọ́ kan nã? nitori bi Sioni ti nrọbi gẹ, bẹ̃li o bi awọn ọmọ rẹ̀. Emi o ha mu wá si irọbi, ki nmá si mu ki o bi? li Oluwa wi: emi o ha mu ni bi, ki nsi sé inu? li Ọlọrun rẹ wi. Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u. Ki ẹnyin ki o le mu ọmú, ki a si fi ọmú itunu rẹ̀ tẹ́ nyin lọrùn; ki ẹnyin ki o ba le fun wàra, ki inu nyin ba sì le dùn si ọ̀pọlọpọ ogo rẹ̀.
Isa 66:7-11 Yoruba Bible (YCE)
“Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ. Kí ìrora obí tó mú un, ó ti bí ọmọkunrin kan. Ta ló gbọ́ irú èyí rí? Ta ló rí irú rẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan, tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan? Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí, kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí? Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ, ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?” Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀, ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu; kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú, ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.
Isa 66:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin. Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀. Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni OLúWA wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí. “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un. Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára; Ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”