Isa 65:1-25
Isa 65:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
A wá mi lọdọ awọn ti kò bere mi; a ri mi lọdọ awọn ti kò wá mi: mo wi fun orilẹ-ède ti a kò pe li orukọ mi pe, Wò mi, wò mi. Ni gbogbo ọjọ ni mo ti na ọwọ́ mi si awọn ọlọtẹ̀ enia, ti nrìn li ọ̀na ti kò dara, nipa ìro ara wọn; Awọn enia ti o nṣọ́ mi ni inu nigbagbogbo kàn mi loju; ti nrubọ ninu agbàla, ti nwọn si nfi turari jona lori pẹpẹ briki. Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn; Ẹniti o wipe, Duro fun ara rẹ, máṣe sunmọ mi; nitori ti mo ṣe mimọ́ jù ọ lọ. Wọnyi li ẹ̃fin ni imu mi, iná ti njo ni gbogbo ọjọ ni. Kiyesi i, a ti kọwe rẹ̀ niwaju mi: emi kì o dakẹ, ṣugbọn emi o gbẹ̀san, ani ẹ̀san si aiya wọn, Aiṣedede nyin, ati aiṣedede awọn baba nyin ṣọkan pọ̀, li Oluwa wi, awọn ẹniti o fi turari jona lori oke-nla, ti nwọn mbu ọla mi kù lori awọn oke kékèké: nitori na li emi o wọ̀n iṣẹ wọn iṣaju, sinu aiya wọn. Bayi ni Oluwa wi, gẹgẹ bi a ti iri ọti-waini titun ninu ìdi eso àjara, ti a si nwipe, Máṣe bà a jẹ nitori ibukun mbẹ ninu rẹ̀: bẹ̃li emi o ṣe nitori awọn iranṣẹ mi, ki emi ki o má ba pa gbogbo wọn run. Emi o si mu iru kan jade ni Jakobu, ati ajogun oke-nla mi lati inu Juda: ayanfẹ mi yio si jogun rẹ̀, awọn iranṣẹ mi yio si gbe ibẹ. Ṣaroni yio di agbo-ẹran, ati afonifoji Akori ibikan fun awọn ọwọ́ ẹran lati dubulẹ ninu rẹ̀, nitori awọn enia mi ti o ti wá mi kiri. Ṣugbọn ẹnyin ti o kọ̀ Oluwa silẹ, ti o gbàgbe oke-nla mimọ́ mi, ti o pèse tabili fun Gadi, ti o si fi ọrẹ mimu kun Meni. Nitorina li emi o ṣe kà nyin fun idà, gbogbo nyin yio wolẹ fun pipa: nitori nigbati mo pè, ẹnyin kò dahùn; nigbati mo sọ̀rọ, ẹnyin kò gbọ́; ṣugbọn ẹnyin ṣe ibi loju mi, ẹnyin si yàn eyiti inu mi kò dùn si. Nitorina bayi ni Oluwa Jehofah wi, Kiyesi i awọn iranṣẹ mi o jẹun, ṣugbọn ebi yio pa ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o mu, ṣugbọn ongbẹ o gbẹ ẹnyin: kiyesi i, awọn iranṣẹ mi o yọ̀, ṣugbọn oju o tì ẹnyin: Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn. Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran: Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi. Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀. Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe. Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu. Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn. Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn. Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn. Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọ̀rọ lọwọ, emi o gbọ́. Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.
Isa 65:1-25 Yoruba Bible (YCE)
Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi. Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé, “Èmi nìyí, èmi nìyí.” Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan; àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára, tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn, tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú, níṣojú mi, nígbà gbogbo. Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà, wọ́n ń sun turari lórí bíríkì. Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú, tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru; àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́. Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí, nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.” Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi, bí iná tí ó ń jó lojoojumọ. Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé, “N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san. N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn, ati ti àwọn baba wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn. “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà, tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́, nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi, n kò ní pa gbogbo wọn run. N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu, àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda. Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀, àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀. Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran, àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí, fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi. “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀, tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi, tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire, tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́. N óo fi yín fún ogun pa, gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn; nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́, ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi; ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí. Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ, ṣugbọn ebi yóo máa pa yín; àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini, ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀, ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn, ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá; ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn. Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi yóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún. Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín. Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn. Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà, yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́, ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà, orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra. Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé, a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.” OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun; a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́, tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn, kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá. Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀, mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn. N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu, inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi. A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́, ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́. Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́, àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún, a óo sọ pé ó kú ikú ègún. Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀; wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀. Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ. Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò, àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù, wọn kò ní bímọ fún jamba; nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́, àwọn ati àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn, kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù, erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára. Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Isa 65:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi; Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi. Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi, Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’ Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi síta sí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle, tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára, tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbo lójú ara mi gan an, wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbà wọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì; wọ́n ń jókòó láàrín ibojì wọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀; tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́; tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’ Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó. “Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi: Èmi kì yóò dákẹ́, ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́; Èmi yóò san án padà sí àyà wọn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,” ni OLúWA wí. “Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré, Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.” Báyìí ni OLúWA wí: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́, nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi; Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run. Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu, àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì; àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé. Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran, àti Àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran, fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi. “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ OLúWA sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán, Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà, àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa; nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn. Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀ Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.” Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: “Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun; ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu, ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin; àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀, ṣùgbọ́n a ó dójútì yin. Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè láti inú ìrora ọkàn yín àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn. Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; OLúWA Olódùmarè yóò sì pa yín, ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun yóò fún ní orúkọ mìíràn Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi. “Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́. “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán; ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé; ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú. Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ, Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́. Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán, wọn kí yóò bímọ fún wàhálà; nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti OLúWA bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn. Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn; nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́. Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni OLúWA wí.