Isa 65:1 - Compare All Versions

Isa 65:1 YBCV (Bibeli Mimọ)

A wá mi lọdọ awọn ti kò bere mi; a ri mi lọdọ awọn ti kò wá mi: mo wi fun orilẹ-ède ti a kò pe li orukọ mi pe, Wò mi, wò mi.

Isa 65:1 YCE (Yoruba Bible)

Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi, ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi. Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé, “Èmi nìyí, èmi nìyí.”

Isa 65:1 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi; àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi. Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi, ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’