Isa 64:8-9
Isa 64:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.
Pín
Kà Isa 64Isa 64:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa. OLUWA má bínú pupọ jù, má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae. Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò, nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.
Pín
Kà Isa 64